The Quran in Yoruba - Surah Duha translated into Yoruba, Surah Ad-Dhuha in Yoruba. We provide accurate translation of Surah Duha in Yoruba - اليوربا, Verses 11 - Surah Number 93 - Page 596.

| وَالضُّحَىٰ (1) (Allahu bura pelu) iyaleta | 
| وَاللَّيْلِ إِذَا سَجَىٰ (2) O tun bura pelu ale nigba ti (ile) ba su | 
| مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ (3) Oluwa re ko pa o ti, ko si binu si o | 
| وَلَلْآخِرَةُ خَيْرٌ لَّكَ مِنَ الْأُولَىٰ (4) Dajudaju orun loore fun o ju aye lo | 
| وَلَسَوْفَ يُعْطِيكَ رَبُّكَ فَتَرْضَىٰ (5) Dajudaju laipe Oluwa re maa fun o ni (oore pupo ni orun). Nitori naa, o si maa yonu si i | 
| أَلَمْ يَجِدْكَ يَتِيمًا فَآوَىٰ (6) Se (Allahu) ko ri o ni omo-orukan ni? O si fun o ni ibugbe | 
| وَوَجَدَكَ ضَالًّا فَهَدَىٰ (7) O si ri o ni alaimona (iyen siwaju isokale imisi). O si fi ona mo o | 
| وَوَجَدَكَ عَائِلًا فَأَغْنَىٰ (8) O tun ri o ni alaini, O si ro o loro | 
| فَأَمَّا الْيَتِيمَ فَلَا تَقْهَرْ (9) Nitori naa, ni ti omo-orukan, ma se je gaba (le e lori) | 
| وَأَمَّا السَّائِلَ فَلَا تَنْهَرْ (10) Ni ti alagbe, ma si se jagbe (mo on) | 
| وَأَمَّا بِنِعْمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثْ (11) Ni ti idera Oluwa re, so o jade |