The Quran in Yoruba - Surah Adiyat translated into Yoruba, Surah Al-Adiyat in Yoruba. We provide accurate translation of Surah Adiyat in Yoruba - اليوربا, Verses 11 - Surah Number 100 - Page 599.

| وَالْعَادِيَاتِ ضَبْحًا (1) Allahu bura pelu awon esin t’o n sare t’o n mi helehele ni oju-ogun | 
| فَالْمُورِيَاتِ قَدْحًا (2) O tun bura pelu awon esin ti patako ese won n sana (nibi ere sisa) | 
| فَالْمُغِيرَاتِ صُبْحًا (3) O tun bura pelu awon esin t’o n kolu ota esin ni owuro kutukutu | 
| فَأَثَرْنَ بِهِ نَقْعًا (4) Won si fi (patako ese won) tu eruku (ile ota) soke | 
| فَوَسَطْنَ بِهِ جَمْعًا (5) Won tun be gija papo pelu re saaarin akojo ota | 
| إِنَّ الْإِنسَانَ لِرَبِّهِ لَكَنُودٌ (6) Dajudaju eniyan ni alaimoore si Oluwa re | 
| وَإِنَّهُ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٌ (7) Dajudaju Allahu si n je Elerii lori iyen | 
| وَإِنَّهُ لِحُبِّ الْخَيْرِ لَشَدِيدٌ (8) Ati pe dajudaju eniyan le gan-an nibi ife oore aye | 
| ۞ أَفَلَا يَعْلَمُ إِذَا بُعْثِرَ مَا فِي الْقُبُورِ (9) Se ko mo pe nigba ti won ba tu ohun t’o wa ninu saree jade (fun ajinde) | 
| وَحُصِّلَ مَا فِي الصُّدُورِ (10) ti won si tu ohun t’o wa ninu igba-aya eda sita patapata | 
| إِنَّ رَبَّهُم بِهِمْ يَوْمَئِذٍ لَّخَبِيرٌ (11) dajudaju Oluwa won ni Alamotan nipa won ni Ojo yen |