Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 102 - البَقَرَة - Page - Juz 1
﴿وَٱتَّبَعُواْ مَا تَتۡلُواْ ٱلشَّيَٰطِينُ عَلَىٰ مُلۡكِ سُلَيۡمَٰنَۖ وَمَا كَفَرَ سُلَيۡمَٰنُ وَلَٰكِنَّ ٱلشَّيَٰطِينَ كَفَرُواْ يُعَلِّمُونَ ٱلنَّاسَ ٱلسِّحۡرَ وَمَآ أُنزِلَ عَلَى ٱلۡمَلَكَيۡنِ بِبَابِلَ هَٰرُوتَ وَمَٰرُوتَۚ وَمَا يُعَلِّمَانِ مِنۡ أَحَدٍ حَتَّىٰ يَقُولَآ إِنَّمَا نَحۡنُ فِتۡنَةٞ فَلَا تَكۡفُرۡۖ فَيَتَعَلَّمُونَ مِنۡهُمَا مَا يُفَرِّقُونَ بِهِۦ بَيۡنَ ٱلۡمَرۡءِ وَزَوۡجِهِۦۚ وَمَا هُم بِضَآرِّينَ بِهِۦ مِنۡ أَحَدٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَيَتَعَلَّمُونَ مَا يَضُرُّهُمۡ وَلَا يَنفَعُهُمۡۚ وَلَقَدۡ عَلِمُواْ لَمَنِ ٱشۡتَرَىٰهُ مَا لَهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنۡ خَلَٰقٖۚ وَلَبِئۡسَ مَا شَرَوۡاْ بِهِۦٓ أَنفُسَهُمۡۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ ﴾
[البَقَرَة: 102]
﴿واتبعوا ما تتلوا الشياطين على ملك سليمان وما كفر سليمان ولكن الشياطين﴾ [البَقَرَة: 102]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Wọ́n sì tẹ̀lé ohun tí àwọn èṣù àlùjànnú ń kà (fún wọn nínú idán) lásìkò ìjọba (Ànábì) Sulaemọ̄n. (Ànábì) Sulaemọ̄n kò sì ṣàì gbàgbọ́, ṣùgbọ́n àwọn èṣù àlùjànnú ni wọ́n ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn ní idán. Àwa kò sì sọ (idán) kalẹ̀ fún àwọn mọlāika méjì náà. (Àmọ́ àwọn èṣù àlùjànnú wọ̀nyí) Hārūt àti Mọ̄rūt ní (ìlú) Bābil (ni wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn nídán). Wọn kò sì níí kọ́ ẹnikẹ́ni àyàfi kí wọ́n wí pé: "Àdánwò ni wá. Nítorí náà, má di kèfèrí." Wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọn yóò fi ṣòpínyà láààrin ọmọnìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn àlùjànnú méjèèjì. - Wọn kò sì lè kó ìnira bá ẹnikẹ́ni àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. - Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ó máa kó ìnira bá wọn, tí kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọ́n kúkú ti mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ra idán, kò níí sí ìpín rere kan fún un ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Aburú sì ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀. tí àwọn onímọ̀ mú wá lórí rẹ̀. Má ṣe ṣíjú wo ìtúmọ̀ mìíràn … bí ìtàn tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn ọtí mímu àti ẹ̀sùn ìpànìyàn kan àwọn mọlāika… Ìpìlẹ̀ àdìsọ́kàn tí a ní sí àwọn mọlāika yó forí sánpọ́n nípa pípe Hārūt àti Mọ̄rūt ní mọlāika. Àwọn mọlāika ni ẹni tí Allāhu ní àfọkàntán sí lórí ìmísí Rẹ̀ tí Ó fi rán wọn. Àwọn sì ni aṣojú Allāhu fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ wo sūrah at-Tahrīm; 66:6 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:26-27…” al-Ƙurtubiy. bí Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìgbàgbọ́ òdodo tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán an níṣẹ́ sí wọn bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn èṣù àlùjànnú kan ń lọ bá àwọn ènìyàn láti máa kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ idán láti máa fi tako ìgbàgbọ́ òdodo tí wọ́n ń gbọ́ lọ́dọ̀ Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Níkété tí ìró aburú yìí détí ìgbọ́ Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’ó páṣẹ láti gba gbogbo àkọsílẹ̀ idán náà lọ́wọ́ wọn. Ó sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ |