Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 158 - البَقَرَة - Page - Juz 2
﴿۞ إِنَّ ٱلصَّفَا وَٱلۡمَرۡوَةَ مِن شَعَآئِرِ ٱللَّهِۖ فَمَنۡ حَجَّ ٱلۡبَيۡتَ أَوِ ٱعۡتَمَرَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِ أَن يَطَّوَّفَ بِهِمَاۚ وَمَن تَطَوَّعَ خَيۡرٗا فَإِنَّ ٱللَّهَ شَاكِرٌ عَلِيمٌ ﴾
[البَقَرَة: 158]
﴿إن الصفا والمروة من شعائر الله فمن حج البيت أو اعتمر فلا﴾ [البَقَرَة: 158]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ Hajj sí Ilé náà tàbí ó ṣe iṣẹ́ ‘Umrah, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un láti rìn yíká (láààrin àpáta) méjèèjì. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fínnú-fíndọ̀ ṣe iṣẹ́ àṣegbọrẹ, dájúdájú Allāhu ni Amoore, Onímọ̀ |