Quran with Yoruba translation - Surah An-Nur ayat 60 - النور - Page - Juz 18
﴿وَٱلۡقَوَٰعِدُ مِنَ ٱلنِّسَآءِ ٱلَّٰتِي لَا يَرۡجُونَ نِكَاحٗا فَلَيۡسَ عَلَيۡهِنَّ جُنَاحٌ أَن يَضَعۡنَ ثِيَابَهُنَّ غَيۡرَ مُتَبَرِّجَٰتِۭ بِزِينَةٖۖ وَأَن يَسۡتَعۡفِفۡنَ خَيۡرٞ لَّهُنَّۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٞ ﴾
[النور: 60]
﴿والقواعد من النساء اللاتي لا يرجون نكاحا فليس عليهن جناح أن يضعن﴾ [النور: 60]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àwọn t’ó ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí nínú àwọn obìnrin, àwọn tí kò retí ìbálòpò oorun ìfẹ́ mọ́, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn láti bọ́ àwọn aṣọ jilbāb wọn sílẹ̀, tí wọn kò sì níí ṣe àfihàn ọ̀ṣọ́ kan síta. Kí wọ́n sì máa wọ aṣọ jilbāb wọn lọ bẹ́ẹ̀ lóore jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀ |