Quran with Yoruba translation - Surah Al-Ma’idah ayat 64 - المَائدة - Page - Juz 6
﴿وَقَالَتِ ٱلۡيَهُودُ يَدُ ٱللَّهِ مَغۡلُولَةٌۚ غُلَّتۡ أَيۡدِيهِمۡ وَلُعِنُواْ بِمَا قَالُواْۘ بَلۡ يَدَاهُ مَبۡسُوطَتَانِ يُنفِقُ كَيۡفَ يَشَآءُۚ وَلَيَزِيدَنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُم مَّآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَ طُغۡيَٰنٗا وَكُفۡرٗاۚ وَأَلۡقَيۡنَا بَيۡنَهُمُ ٱلۡعَدَٰوَةَ وَٱلۡبَغۡضَآءَ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ كُلَّمَآ أَوۡقَدُواْ نَارٗا لِّلۡحَرۡبِ أَطۡفَأَهَا ٱللَّهُۚ وَيَسۡعَوۡنَ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَسَادٗاۚ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُفۡسِدِينَ ﴾
[المَائدة: 64]
﴿وقالت اليهود يد الله مغلولة غلت أيديهم ولعنوا بما قالوا بل يداه﴾ [المَائدة: 64]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àwọn yẹhudi wí pé: "Ọwọ́ Allāhu wà ní dídì pa." A di ọwọ́ wọn pa. A sì ṣẹ́bi lé wọn nítorí ohun tí wọ́n wí. Àmọ́ ọwọ́ Rẹ̀ méjèèjì wà ní títẹ́ sílẹ̀. Ó sì ń tọrẹ bí Ó ṣe fẹ́. Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ̀ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. A sì ju ọ̀tá àti ìkórira sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá dáná ogun, Allāhu sì máa paná rẹ̀. Wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́ |