Quran with Yoruba translation - Surah Al-A‘raf ayat 179 - الأعرَاف - Page - Juz 9
﴿وَلَقَدۡ ذَرَأۡنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ لَهُمۡ قُلُوبٞ لَّا يَفۡقَهُونَ بِهَا وَلَهُمۡ أَعۡيُنٞ لَّا يُبۡصِرُونَ بِهَا وَلَهُمۡ ءَاذَانٞ لَّا يَسۡمَعُونَ بِهَآۚ أُوْلَٰٓئِكَ كَٱلۡأَنۡعَٰمِ بَلۡ هُمۡ أَضَلُّۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡغَٰفِلُونَ ﴾
[الأعرَاف: 179]
﴿ولقد ذرأنا لجهنم كثيرا من الجن والإنس لهم قلوب لا يفقهون بها﴾ [الأعرَاف: 179]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Dájúdájú A ti dá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àlùjànnú fún iná Jahanamọ (nítorí pé) wọ́n ní ọkàn, wọn kò sì fi gbọ́ àgbọ́yé; wọ́n ní ojú, wọn kò sì fi ríran; wọ́n ní etí, wọn kò sì fi gbọ́ràn. Àwọn wọ̀nyẹn dà bí ẹran-ọ̀sìn. Wọ́n wulẹ̀ sọnù jùlọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni afọ́nú-fọ́ra |