Quran with Yoruba translation - Surah Al-A‘raf ayat 190 - الأعرَاف - Page - Juz 9
﴿فَلَمَّآ ءَاتَىٰهُمَا صَٰلِحٗا جَعَلَا لَهُۥ شُرَكَآءَ فِيمَآ ءَاتَىٰهُمَاۚ فَتَعَٰلَى ٱللَّهُ عَمَّا يُشۡرِكُونَ ﴾
[الأعرَاف: 190]
﴿فلما آتاهما صالحا جعلا له شركاء فيما آتاهما فتعالى الله عما يشركون﴾ [الأعرَاف: 190]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ṣùgbọ́n nígbà tí Allāhu fún àwọn méjèèjì ní ọmọ rere, wọ́n sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Un nípasẹ̀ ohun tí Ó fún àwọn méjèèjì. Allāhu sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I. kí ènìyàn wá sọ ọmọ náà ni “ ‘abdu-ṣṣams ‘abdul-ƙọmọr” dípò “ ‘abdullāh bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ibn Kathīr ka ìtàn náà mọ́ ara ìtàn irọ́ àwọn ọmọ Isrọ̄’īl. Àmọ́ ìtàn tí ẹnu kùn yìí kúkú ni àwọn tí wọ́n gbà pé Ànábì Ādam (alaehi sọlāt wa salām) àti ìyá wa Hawā’ (rọdiyallahu anhā) ni tọkọ tìyàwó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí rí mú lò láti fi túmọ̀ āyah náà. Kókó ìtàn náà ni pé nígbà tí ìyá wa Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) lóyún àmọ́ kò forí balẹ̀ fún Èṣù rárá. Ìyẹn wà nínú ìwé Luku 4: 1-13. Nítorí náà Allāhu nìkan ṣoṣo ni kò lè ṣàṣìṣe |