Quran with Yoruba translation - Surah Al-A‘raf ayat 189 - الأعرَاف - Page - Juz 9
﴿۞ هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ وَجَعَلَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا لِيَسۡكُنَ إِلَيۡهَاۖ فَلَمَّا تَغَشَّىٰهَا حَمَلَتۡ حَمۡلًا خَفِيفٗا فَمَرَّتۡ بِهِۦۖ فَلَمَّآ أَثۡقَلَت دَّعَوَا ٱللَّهَ رَبَّهُمَا لَئِنۡ ءَاتَيۡتَنَا صَٰلِحٗا لَّنَكُونَنَّ مِنَ ٱلشَّٰكِرِينَ ﴾
[الأعرَاف: 189]
﴿هو الذي خلقكم من نفس واحدة وجعل منها زوجها ليسكن إليها فلما﴾ [الأعرَاف: 189]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Allāhu) Òun ni Ẹni t’Ó da yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Ó sì dá aya fún un láti ara rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ̀gbádùn ìgbépọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí ọkọ súnmọ́ ìyàwó rẹ̀, tí ó sì ru ẹrù (àtọ̀) fífúyẹ́. Ó sì rù ú kiri. Nígbà tí ó sì diwọ́ disẹ̀ sínú tán, àwọn méjèèjì pe Allāhu Olúwa wọn pé: “Tí O bá fún wa ni ọmọ rere (t’ó pé ní ẹ̀dá), dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.” |