Quran with Yoruba translation - Surah Al-Kahf ayat 17 - الكَهف - Page - Juz 15
﴿۞ وَتَرَى ٱلشَّمۡسَ إِذَا طَلَعَت تَّزَٰوَرُ عَن كَهۡفِهِمۡ ذَاتَ ٱلۡيَمِينِ وَإِذَا غَرَبَت تَّقۡرِضُهُمۡ ذَاتَ ٱلشِّمَالِ وَهُمۡ فِي فَجۡوَةٖ مِّنۡهُۚ ذَٰلِكَ مِنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِۗ مَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَهُوَ ٱلۡمُهۡتَدِۖ وَمَن يُضۡلِلۡ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ وَلِيّٗا مُّرۡشِدٗا ﴾
[الكَهف: 17]
﴿وترى الشمس إذا طلعت تزاور عن كهفهم ذات اليمين وإذا غربت تقرضهم﴾ [الكَهف: 17]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni O máa rí òòrùn nígbà tí ó bá yọ, ó máa yẹ̀bá kúrò níbi ihò wọn sí ọwọ́ ọ̀tún. Nígbà tí ó bá tún wọ̀, ó máa fi wọ́n sílẹ̀ sí ọwọ́ òsì. Wọ́n sì wà nínú àyè tí ó fẹjú nínú ihò àpáta. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ atọ́ni-sọ́nà kan fún un |