Quran with Yoruba translation - Surah Al-Kahf ayat 19 - الكَهف - Page - Juz 15
﴿وَكَذَٰلِكَ بَعَثۡنَٰهُمۡ لِيَتَسَآءَلُواْ بَيۡنَهُمۡۚ قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ كَمۡ لَبِثۡتُمۡۖ قَالُواْ لَبِثۡنَا يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖۚ قَالُواْ رَبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِمَا لَبِثۡتُمۡ فَٱبۡعَثُوٓاْ أَحَدَكُم بِوَرِقِكُمۡ هَٰذِهِۦٓ إِلَى ٱلۡمَدِينَةِ فَلۡيَنظُرۡ أَيُّهَآ أَزۡكَىٰ طَعَامٗا فَلۡيَأۡتِكُم بِرِزۡقٖ مِّنۡهُ وَلۡيَتَلَطَّفۡ وَلَا يُشۡعِرَنَّ بِكُمۡ أَحَدًا ﴾
[الكَهف: 19]
﴿وكذلك بعثناهم ليتساءلوا بينهم قال قائل منهم كم لبثتم قالوا لبثنا يوما﴾ [الكَهف: 19]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Báyẹn (ni wọ́n wà) tí A fi gbé wọn dìde padà nítorí kí wọ́n lè bi ara wọn léèrè ìbéèrè. Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ìgbà wo lẹ ti wà níbí?” Wọ́n sọ pé: “A wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí ìdajì ọjọ́.” Wọ́n sọ pé: “Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ìgbà tí ẹ ti wà níbí.” Nítorí náà, ẹ gbé ọ̀kan nínú yín dìde lọ sí inú ìlú pẹ̀lú owó fàdákà yín yìí. Kí ó wo èwó nínú oúnjẹ ìlú l’ó mọ́ jùlọ, kí ó sì mú àsè wá fun yín nínú rẹ̀. Kí ó ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnì kan kan fura si yín |