Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 144 - البَقَرَة - Page - Juz 2
﴿قَدۡ نَرَىٰ تَقَلُّبَ وَجۡهِكَ فِي ٱلسَّمَآءِۖ فَلَنُوَلِّيَنَّكَ قِبۡلَةٗ تَرۡضَىٰهَاۚ فَوَلِّ وَجۡهَكَ شَطۡرَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَحَيۡثُ مَا كُنتُمۡ فَوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ شَطۡرَهُۥۗ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ لَيَعۡلَمُونَ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّهِمۡۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا يَعۡمَلُونَ ﴾
[البَقَرَة: 144]
﴿قد نرى تقلب وجهك في السماء فلنولينك قبلة ترضاها فول وجهك شطر﴾ [البَقَرَة: 144]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni A kúkú rí yíyí tí ò ń yí ojú rẹ sí sánmọ̀. Nítorí náà, A ó dojú rẹ kọ Ƙiblah kan tí o yọ́nú sí; nítorí náà, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram (ní Mọkkah). Ibikíbi tí ẹ bá tún wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀. Dájúdájú àwọn tí A fún ní Tírà kúkú mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni (àṣẹ Ƙiblah) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ |