Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 233 - البَقَرَة - Page - Juz 2
﴿۞ وَٱلۡوَٰلِدَٰتُ يُرۡضِعۡنَ أَوۡلَٰدَهُنَّ حَوۡلَيۡنِ كَامِلَيۡنِۖ لِمَنۡ أَرَادَ أَن يُتِمَّ ٱلرَّضَاعَةَۚ وَعَلَى ٱلۡمَوۡلُودِ لَهُۥ رِزۡقُهُنَّ وَكِسۡوَتُهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ لَا تُكَلَّفُ نَفۡسٌ إِلَّا وُسۡعَهَاۚ لَا تُضَآرَّ وَٰلِدَةُۢ بِوَلَدِهَا وَلَا مَوۡلُودٞ لَّهُۥ بِوَلَدِهِۦۚ وَعَلَى ٱلۡوَارِثِ مِثۡلُ ذَٰلِكَۗ فَإِنۡ أَرَادَا فِصَالًا عَن تَرَاضٖ مِّنۡهُمَا وَتَشَاوُرٖ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَاۗ وَإِنۡ أَرَدتُّمۡ أَن تَسۡتَرۡضِعُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُمۡ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ إِذَا سَلَّمۡتُم مَّآ ءَاتَيۡتُم بِٱلۡمَعۡرُوفِۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ ﴾
[البَقَرَة: 233]
﴿والوالدات يرضعن أولادهن حولين كاملين لمن أراد أن يتم الرضاعة وعلى المولود﴾ [البَقَرَة: 233]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àwọn abiyamọ yóò máa fún àwọn ọmọ wọn ní ọyàn mu fún ọdún méjì gbáko, fún ẹni tí ó bá fẹ́ parí (àsìkò) ìfọ́mọlọ́yàn. Ojúṣe ni fún ẹni tí wọ́n bímọ fún láti máa ṣe (ètò) ìjẹ-ìmu wọn àti aṣọ wọn ní ọ̀nà t’ó dára. Wọn kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Wọn kò níí kó ìnira bá abiyamọ nítorí ọmọ rẹ̀. Wọn kò sì níí kó ìnira bá ẹni tí wọ́n bímọ fún nítorí ọmọ rẹ̀. Irú (ojúṣe) yẹn tún ń bẹ fún olùjogún. Tí àwọn méjèèjì bá sì fẹ́ gba ọyàn l’ẹ́nu ọmọ pẹ̀lú ìpanupọ̀ àti àṣàrò àwọn méjèèjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì. Tí ẹ bá sì fẹ́ gba ẹni tí ó máa fún àwọn ọmọ yín lọ́yàn mu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín, tí ẹ bá ti fún wọn ní ohun tí ẹ fẹ́ fún wọn (ní owó-ọ̀yà) ní ọ̀nà t’ó dára. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ |