Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 249 - البَقَرَة - Page - Juz 2
﴿فَلَمَّا فَصَلَ طَالُوتُ بِٱلۡجُنُودِ قَالَ إِنَّ ٱللَّهَ مُبۡتَلِيكُم بِنَهَرٖ فَمَن شَرِبَ مِنۡهُ فَلَيۡسَ مِنِّي وَمَن لَّمۡ يَطۡعَمۡهُ فَإِنَّهُۥ مِنِّيٓ إِلَّا مَنِ ٱغۡتَرَفَ غُرۡفَةَۢ بِيَدِهِۦۚ فَشَرِبُواْ مِنۡهُ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنۡهُمۡۚ فَلَمَّا جَاوَزَهُۥ هُوَ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ قَالُواْ لَا طَاقَةَ لَنَا ٱلۡيَوۡمَ بِجَالُوتَ وَجُنُودِهِۦۚ قَالَ ٱلَّذِينَ يَظُنُّونَ أَنَّهُم مُّلَٰقُواْ ٱللَّهِ كَم مِّن فِئَةٖ قَلِيلَةٍ غَلَبَتۡ فِئَةٗ كَثِيرَةَۢ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ مَعَ ٱلصَّٰبِرِينَ ﴾
[البَقَرَة: 249]
﴿فلما فصل طالوت بالجنود قال إن الله مبتليكم بنهر فمن شرب منه﴾ [البَقَرَة: 249]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Nígbà tí Tọ̄lūt jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu máa fi odò kan dan yín wò. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú rẹ̀, kì í ṣe ẹni mi. Ẹni tí kò bá tọ́ ọ wò dájúdájú òun ni ẹni mi, àyàfi ẹni tí ó bá bu ìwọ̀n ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ kan mu.” (Ṣùgbọ́n) wọ́n mu nínú rẹ̀ àfi díẹ̀ nínú wọn. Nígbà tí òun àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ sọdá odò náà, wọ́n sọ pé: “Kò sí agbára kan fún wa lónìí tí a lè fi k’ojú Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” Àwọn t’ó mọ̀ pé dájúdájú àwọn máa pàdé Allāhu, wọ́n sọ pé: "Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ (ogun) kékeré t’ó ti ṣẹ́gun ìjọ (ogun) púpọ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onísùúrù |