Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 260 - البَقَرَة - Page - Juz 3
﴿وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِـۧمُ رَبِّ أَرِنِي كَيۡفَ تُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰۖ قَالَ أَوَلَمۡ تُؤۡمِنۖ قَالَ بَلَىٰ وَلَٰكِن لِّيَطۡمَئِنَّ قَلۡبِيۖ قَالَ فَخُذۡ أَرۡبَعَةٗ مِّنَ ٱلطَّيۡرِ فَصُرۡهُنَّ إِلَيۡكَ ثُمَّ ٱجۡعَلۡ عَلَىٰ كُلِّ جَبَلٖ مِّنۡهُنَّ جُزۡءٗا ثُمَّ ٱدۡعُهُنَّ يَأۡتِينَكَ سَعۡيٗاۚ وَٱعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٞ ﴾
[البَقَرَة: 260]
﴿وإذ قال إبراهيم رب أرني كيف تحي الموتى قال أو لم تؤمن﴾ [البَقَرَة: 260]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Olúwa mi, fi hàn mí bí Ìwọ yó ṣe sọ àwọn òkú di alààyè." (Allāhu) sọ pé: “Ṣé ìwọ kò gbàgbọ́ ni?” Ó sọ pé: “Rárá, ṣùgbọ́n kí ọkàn mi lè balẹ̀ ni”. (Allāhu) sọ pé: "Mú mẹ́rin nínú àwọn ẹyẹ, kí o so wọ́n mọ́lẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ (kí o pa wọ́n, kí o sì gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn). Lẹ́yìn náà, fi ìpín nínú wọn sórí àpáta kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, pè wọ́n. Wọ́n máa sáré wá bá ọ. Kí o sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n |