Quran with Yoruba translation - Surah An-Nur ayat 35 - النور - Page - Juz 18
﴿۞ ٱللَّهُ نُورُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ مَثَلُ نُورِهِۦ كَمِشۡكَوٰةٖ فِيهَا مِصۡبَاحٌۖ ٱلۡمِصۡبَاحُ فِي زُجَاجَةٍۖ ٱلزُّجَاجَةُ كَأَنَّهَا كَوۡكَبٞ دُرِّيّٞ يُوقَدُ مِن شَجَرَةٖ مُّبَٰرَكَةٖ زَيۡتُونَةٖ لَّا شَرۡقِيَّةٖ وَلَا غَرۡبِيَّةٖ يَكَادُ زَيۡتُهَا يُضِيٓءُ وَلَوۡ لَمۡ تَمۡسَسۡهُ نَارٞۚ نُّورٌ عَلَىٰ نُورٖۚ يَهۡدِي ٱللَّهُ لِنُورِهِۦ مَن يَشَآءُۚ وَيَضۡرِبُ ٱللَّهُ ٱلۡأَمۡثَٰلَ لِلنَّاسِۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ ﴾
[النور: 35]
﴿الله نور السموات والأرض مثل نوره كمشكاة فيها مصباح المصباح في زجاجة﴾ [النور: 35]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Allāhu ni Olùtan-ìmọ́lẹ̀ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àpèjúwe ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ dà bí òpó àtùpà kan tí àtùpà wà nínú rẹ̀. Àtùpà náà sì wà nínú díńgí. Díńgí náà dà bí ìràwọ̀ kan t’ó ń tàn yànrànyànràn. Wọ́n ń tan (ìmọ́lẹ̀ náà) láti ara igi ìbùkún kan, igi zaetūn. Kì í gba ìmọ́lẹ̀ nígbà tí òòrùn bá ń yọ jáde tàbí nígbà tí òòrùn bá ń wọ̀. Epo (ìmọ́lẹ̀) rẹ̀ fẹ́ẹ̀ dá mú ìmọ́lẹ̀ wá, iná ìbáà má dé ibẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ lórí ìmọ́lẹ̀ ni. Allāhu ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí (ọ̀nà) ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Allāhu ń fi àwọn àkàwé lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan |