Quran with Yoruba translation - Surah Al-Ahzab ayat 33 - الأحزَاب - Page - Juz 22
﴿وَقَرۡنَ فِي بُيُوتِكُنَّ وَلَا تَبَرَّجۡنَ تَبَرُّجَ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِ ٱلۡأُولَىٰۖ وَأَقِمۡنَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتِينَ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَطِعۡنَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓۚ إِنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُذۡهِبَ عَنكُمُ ٱلرِّجۡسَ أَهۡلَ ٱلۡبَيۡتِ وَيُطَهِّرَكُمۡ تَطۡهِيرٗا ﴾
[الأحزَاب: 33]
﴿وقرن في بيوتكن ولا تبرجن تبرج الجاهلية الأولى وأقمن الصلاة وآتين الزكاة﴾ [الأحزَاب: 33]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹ fìdí mọ́lé yín. Ẹ má ṣe fi ara àti ọ̀ṣọ́ hàn níta gẹ́gẹ́ bí ti ìfara-fọ̀ṣọ́-hàn ìgbà àìmọ̀kan àkọ́kọ́ (ìyẹn, ṣíwájú kí ẹ t’ó di mùsùlùmí). Ẹ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu kàn ń gbèrò láti mú ẹ̀gbin kúrò lára yín, ẹ̀yin ará ilé (Ànábì). Àti pé Ó (kàn ń gbèrò láti) fọ̀ yín mọ́ tónítóní ni |