Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 35 - النِّسَاء - Page - Juz 5
﴿وَإِنۡ خِفۡتُمۡ شِقَاقَ بَيۡنِهِمَا فَٱبۡعَثُواْ حَكَمٗا مِّنۡ أَهۡلِهِۦ وَحَكَمٗا مِّنۡ أَهۡلِهَآ إِن يُرِيدَآ إِصۡلَٰحٗا يُوَفِّقِ ٱللَّهُ بَيۡنَهُمَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا خَبِيرٗا ﴾
[النِّسَاء: 35]
﴿وإن خفتم شقاق بينهما فابعثوا حكما من أهله وحكما من أهلها إن﴾ [النِّسَاء: 35]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Tí ẹ bà sì mọ̀ pé ìyapa wà láààrin àwọn méjèèjì, ẹ gbé olóye kan dìde láti inú ẹbí ọkọ àti olóye kan láti inú ẹbí ìyàwó. Tí àwọn (tọkọ tìyàwó) méjèèjì bá ń fẹ́ àtúnṣe, Allāhu yóò fi àwọn (olóye méjèèjì) ṣe kòńgẹ́ àtúnṣe lórí ọ̀rọ̀ ààrin wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alámọ̀tán |