×

Awon okunrin ni opomulero (alase) fun awon obinrin nitori pe Allahu s’oore 4:34 Yoruba translation

Quran infoYorubaSurah An-Nisa’ ⮕ (4:34) ayat 34 in Yoruba

4:34 Surah An-Nisa’ ayat 34 in Yoruba (اليوربا)

Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 34 - النِّسَاء - Page - Juz 5

﴿ٱلرِّجَالُ قَوَّٰمُونَ عَلَى ٱلنِّسَآءِ بِمَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ وَبِمَآ أَنفَقُواْ مِنۡ أَمۡوَٰلِهِمۡۚ فَٱلصَّٰلِحَٰتُ قَٰنِتَٰتٌ حَٰفِظَٰتٞ لِّلۡغَيۡبِ بِمَا حَفِظَ ٱللَّهُۚ وَٱلَّٰتِي تَخَافُونَ نُشُوزَهُنَّ فَعِظُوهُنَّ وَٱهۡجُرُوهُنَّ فِي ٱلۡمَضَاجِعِ وَٱضۡرِبُوهُنَّۖ فَإِنۡ أَطَعۡنَكُمۡ فَلَا تَبۡغُواْ عَلَيۡهِنَّ سَبِيلًاۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيّٗا كَبِيرٗا ﴾
[النِّسَاء: 34]

Awon okunrin ni opomulero (alase) fun awon obinrin nitori pe Allahu s’oore ajulo fun apa kan won lori apa kan ati nitori ohun ti won n na ninu dukia won. Awon obinrin rere ni awon olutele-ase (Allahu ati ase oko), awon oluso-eto oko ni koro fun wi pe Allahu so (eto tiwon naa fun won lodo oko won). Awon ti e si n paya orikunkun won, e se waasi fun won, e takete si ibusun won, e lu won. Ti won ba si tele ase yin, e ma se fi ona kan wa won nija. Dajudaju Allahu ga, O tobi

❮ Previous Next ❯

ترجمة: الرجال قوامون على النساء بما فضل الله بعضهم على بعض وبما أنفقوا, باللغة اليوربا

﴿الرجال قوامون على النساء بما فضل الله بعضهم على بعض وبما أنفقوا﴾ [النِّسَاء: 34]

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Àwọn ọkùnrin ni òpómúléró (aláṣẹ) fún àwọn obìnrin nítorí pé Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan àti nítorí ohun tí wọ́n ń ná nínú dúkìá wọn. Àwọn obìnrin rere ni àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ (Allāhu àti àṣẹ ọkọ), àwọn olùṣọ́-ẹ̀tọ́ ọkọ ní kọ̀rọ̀ fún wí pé Allāhu ṣọ́ (ẹ̀tọ́ tiwọn náà fún wọn lọ́dọ̀ ọkọ wọn). Àwọn tí ẹ sì ń páyà oríkunkun wọn, ẹ ṣe wáàsí fún wọn, ẹ takété sí ibùsùn wọn, ẹ lù wọ́n. Tí wọ́n bá sì tẹ̀lé àṣẹ yín, ẹ má ṣe fí ọ̀nà kan wá wọn níjà. Dájúdájú Allāhu ga, Ó tóbi
❮ Previous Next ❯

Verse in more languages

Transliteration Bangla Bosnian German English Persian French Hindi Indonesian Kazakh Dutch Russian Spanish Turkish Urdu Uzbek