Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 43 - النِّسَاء - Page - Juz 5
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقۡرَبُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنتُمۡ سُكَٰرَىٰ حَتَّىٰ تَعۡلَمُواْ مَا تَقُولُونَ وَلَا جُنُبًا إِلَّا عَابِرِي سَبِيلٍ حَتَّىٰ تَغۡتَسِلُواْۚ وَإِن كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوۡ جَآءَ أَحَدٞ مِّنكُم مِّنَ ٱلۡغَآئِطِ أَوۡ لَٰمَسۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَلَمۡ تَجِدُواْ مَآءٗ فَتَيَمَّمُواْ صَعِيدٗا طَيِّبٗا فَٱمۡسَحُواْ بِوُجُوهِكُمۡ وَأَيۡدِيكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَفُوًّا غَفُورًا ﴾
[النِّسَاء: 43]
﴿ياأيها الذين آمنوا لا تقربوا الصلاة وأنتم سكارى حتى تعلموا ما تقولون﴾ [النِّسَاء: 43]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe súnmọ́ ìrun kíkí nígbà tí ọtí bá ń pa yín títí ẹ máa fi mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ àti àwọn oníjánnábà, àfi àwọn olùkọjá nínú mọ́sálásí, títí ẹ máa fi wẹ̀ (ìwẹ̀ jánnábà). Tí ẹ bá sì jẹ́ aláìsàn tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ọ̀kan nínú yín dé láti ibi ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ẹ súnmọ́ obínrin (yín), tí ẹ kò rí omi, ẹ fi erùpẹ̀ t’ó dára ṣe táyàmọ́mù; ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòójúkúrò, Aláforíjìn |