Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 78 - النِّسَاء - Page - Juz 5
﴿أَيۡنَمَا تَكُونُواْ يُدۡرِككُّمُ ٱلۡمَوۡتُ وَلَوۡ كُنتُمۡ فِي بُرُوجٖ مُّشَيَّدَةٖۗ وَإِن تُصِبۡهُمۡ حَسَنَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِكَۚ قُلۡ كُلّٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ فَمَالِ هَٰٓؤُلَآءِ ٱلۡقَوۡمِ لَا يَكَادُونَ يَفۡقَهُونَ حَدِيثٗا ﴾
[النِّسَاء: 78]
﴿أينما تكونوا يدرككم الموت ولو كنتم في بروج مشيدة وإن تصبهم حسنة﴾ [النِّسَاء: 78]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ibikíbi tí ẹ bá wà, ikú yóò pàdé yín, ẹ̀yin ìbáà wà nínú odi ilé gíga fíofío. Tí oore (ìkógun) kan bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Tí aburú (ìfọ́gun) kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Sọ pé: “Gbogbo rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kí l’ó ń ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí ná, tí wọn kò fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan |