Quran with Yoruba translation - Surah Fussilat ayat 10 - فُصِّلَت - Page - Juz 24
﴿وَجَعَلَ فِيهَا رَوَٰسِيَ مِن فَوۡقِهَا وَبَٰرَكَ فِيهَا وَقَدَّرَ فِيهَآ أَقۡوَٰتَهَا فِيٓ أَرۡبَعَةِ أَيَّامٖ سَوَآءٗ لِّلسَّآئِلِينَ ﴾
[فُصِّلَت: 10]
﴿وجعل فيها رواسي من فوقها وبارك فيها وقدر فيها أقواتها في أربعة﴾ [فُصِّلَت: 10]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ó sì fi àwọn àpáta sínú ilẹ̀ láti òkè rẹ̀. Ó fi ìbùkún sínú rẹ̀. Ó sì pèbùbù àwọn arísìkí (àti ohun àmúsọrọ̀) sínú rẹ̀ láààrin ọjọ́ mẹ́rin. (Àwọn ọjọ́ náà) dọ́gba (síra wọn) fún àwọn olùbèèrè (nípa rẹ̀). ó jẹyọ nínú wọn pé “Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà.” Ó wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:54 n̄ǹkan náà kò níí dòhun àfi pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”. Àwọn ẹ̀dá tí kò bá sì jẹmọ́ èròjà ìṣẹ̀dá tàbí àwọn ẹ̀dá tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sọ nípa èròjà ìṣẹ̀dá wọn fún wa Allāhu l’Ó kúkú nímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ àwọn ẹ̀dá kan di ẹ̀dá pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn” nìkan. Àwọn ẹ̀dá kan sì di ẹ̀dá nípasẹ̀ èròjà ìṣẹ̀dá àti gbólóhùn “kunfayakūn”. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀nà tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà gbólóhùn “kunfayakūn” t’ó jẹ́ ti Allāhu nìkan ṣoṣo kò lè sọ Allāhu di olùkánjú. Ìkánjú kì í ṣe ìròyìn rere fún Allāhu. Bí Allāhu ṣe gbàròyìn pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn” |