Quran with Yoruba translation - Surah Al-Ma’idah ayat 32 - المَائدة - Page - Juz 6
﴿مِنۡ أَجۡلِ ذَٰلِكَ كَتَبۡنَا عَلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ أَنَّهُۥ مَن قَتَلَ نَفۡسَۢا بِغَيۡرِ نَفۡسٍ أَوۡ فَسَادٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَكَأَنَّمَا قَتَلَ ٱلنَّاسَ جَمِيعٗا وَمَنۡ أَحۡيَاهَا فَكَأَنَّمَآ أَحۡيَا ٱلنَّاسَ جَمِيعٗاۚ وَلَقَدۡ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُنَا بِٱلۡبَيِّنَٰتِ ثُمَّ إِنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُم بَعۡدَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡأَرۡضِ لَمُسۡرِفُونَ ﴾
[المَائدة: 32]
﴿من أجل ذلك كتبنا على بني إسرائيل أنه من قتل نفسا بغير﴾ [المَائدة: 32]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Nítorí ìyẹn, A sì ṣe é ní òfin fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí (ènìyàn) kan láìjẹ́ nítorí pípa ẹ̀mí (ènìyàn) kan tàbí ṣíṣe ìbàjẹ́ kan lórí ilẹ̀, ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú ẹ̀mí (ènìyàn) ṣẹ̀mí, ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá. Àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì ti wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn lẹ́yìn ìyẹn ni alákọyọ lórí ilẹ̀ |