Quran with Yoruba translation - Surah Al-Anfal ayat 42 - الأنفَال - Page - Juz 10
﴿إِذۡ أَنتُم بِٱلۡعُدۡوَةِ ٱلدُّنۡيَا وَهُم بِٱلۡعُدۡوَةِ ٱلۡقُصۡوَىٰ وَٱلرَّكۡبُ أَسۡفَلَ مِنكُمۡۚ وَلَوۡ تَوَاعَدتُّمۡ لَٱخۡتَلَفۡتُمۡ فِي ٱلۡمِيعَٰدِ وَلَٰكِن لِّيَقۡضِيَ ٱللَّهُ أَمۡرٗا كَانَ مَفۡعُولٗا لِّيَهۡلِكَ مَنۡ هَلَكَ عَنۢ بَيِّنَةٖ وَيَحۡيَىٰ مَنۡ حَيَّ عَنۢ بَيِّنَةٖۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَسَمِيعٌ عَلِيمٌ ﴾
[الأنفَال: 42]
﴿إذ أنتم بالعدوة الدنيا وهم بالعدوة القصوى والركب أسفل منكم ولو تواعدتم﴾ [الأنفَال: 42]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀yin wà ní etí kòtò t’ó súnmọ́ (ìlú Mọdīnah), àwọn (kèfèrí) sì wà ní etí kòtò t’ó jìnnà sí (ìlú Mọdīnah), àwọn kèfèrí kan t’ó ń gun n̄ǹkan ìgùn (bọ̀ láti ìrìn-àjò òkòwò), wọ́n sì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ tiyín. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin àti àwọn kèfèrí jọ mú ọjọ́ fún ogun náà ni, ẹ̀yin ìbá yapa àdéhùn náà, ṣùgbọ́n (ogun náà ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ; nítorí kí ẹni tí ó máa parun (sínú àìgbàgbọ́) lè parun nípasẹ̀ ẹ̀rí t’ó yanjú, kí ẹni t’ó sì máa yè (nínú ìgbàgbọ́ òdodo) lè yè nípasẹ̀ ẹ̀rí t’ó yanjú. Àti pé dájúdájú Allāhu kúkú ni Olùgbọ́, Onímọ̀ |