يَا أَيُّهَا الْمُزَّمِّلُ (1) Iwo oludasobora |
قُمِ اللَّيْلَ إِلَّا قَلِيلًا (2) Dide (kirun) ni oru ayafi fun igba die |
نِّصْفَهُ أَوِ انقُصْ مِنْهُ قَلِيلًا (3) Lo ilaji re tabi din die ku ninu re |
أَوْ زِدْ عَلَيْهِ وَرَتِّلِ الْقُرْآنَ تَرْتِيلًا (4) Tabi fi kun un. Ki o si ke al-Ƙur’an ni pelepele |
إِنَّا سَنُلْقِي عَلَيْكَ قَوْلًا ثَقِيلًا (5) Dajudaju Awa maa gbe oro t’o lagbara fun o |
إِنَّ نَاشِئَةَ اللَّيْلِ هِيَ أَشَدُّ وَطْئًا وَأَقْوَمُ قِيلًا (6) Dajudaju idide kirun loru, o wonu okan julo, o si dara julo fun kike (al-Ƙur’an) |
إِنَّ لَكَ فِي النَّهَارِ سَبْحًا طَوِيلًا (7) Dajudaju ise pupo wa fun o ni osan |
وَاذْكُرِ اسْمَ رَبِّكَ وَتَبَتَّلْ إِلَيْهِ تَبْتِيلًا (8) Ranti oruko Oluwa re. Ki o si da okan ko O patapata |
رَّبُّ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَاتَّخِذْهُ وَكِيلًا (9) Oluwa ibuyo oorun ati ibuwo oorun, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, mu Un ni Alafeyinti |
وَاصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَاهْجُرْهُمْ هَجْرًا جَمِيلًا (10) Ki o si se suuru lori ohun ti won n wi. Pa won ti ni ipati t’o rewa |
وَذَرْنِي وَالْمُكَذِّبِينَ أُولِي النَّعْمَةِ وَمَهِّلْهُمْ قَلِيلًا (11) Fi Mi da awon olupe-ododo-niro, awon oloro. Ki o si lora fun won fun igba die |
إِنَّ لَدَيْنَا أَنكَالًا وَجَحِيمًا (12) Dajudaju sekeseke ati Ina Jehim n be lodo Wa |
وَطَعَامًا ذَا غُصَّةٍ وَعَذَابًا أَلِيمًا (13) Ounje hafunhafun ati iya eleta-elero (tun wa fun won) |
يَوْمَ تَرْجُفُ الْأَرْضُ وَالْجِبَالُ وَكَانَتِ الْجِبَالُ كَثِيبًا مَّهِيلًا (14) Ni ojo ti ile ati awon apata yoo maa mi titi pelu ohun igbe lile. Awon apata si maa di yanrin ti won kojo ti won tuka |
إِنَّا أَرْسَلْنَا إِلَيْكُمْ رَسُولًا شَاهِدًا عَلَيْكُمْ كَمَا أَرْسَلْنَا إِلَىٰ فِرْعَوْنَ رَسُولًا (15) Dajudaju Awa ran Ojise kan nise si yin (ti o je) olujerii lori yin gege bi A se ran Ojise kan nise si Fir‘aon |
فَعَصَىٰ فِرْعَوْنُ الرَّسُولَ فَأَخَذْنَاهُ أَخْذًا وَبِيلًا (16) Sugbon Fir‘aon yapa Ojise naa. A si gba a mu ni igbamu lile |
فَكَيْفَ تَتَّقُونَ إِن كَفَرْتُمْ يَوْمًا يَجْعَلُ الْوِلْدَانَ شِيبًا (17) Ti eyin ba sai gbagbo, bawo ni eyin yoo se beru ojo kan t’o maa mu awon omode hewu |
السَّمَاءُ مُنفَطِرٌ بِهِ ۚ كَانَ وَعْدُهُ مَفْعُولًا (18) Sanmo si maa faya perepere ninu re. Adehun Re je ohun ti o maa se |
إِنَّ هَٰذِهِ تَذْكِرَةٌ ۖ فَمَن شَاءَ اتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِ سَبِيلًا (19) Dajudaju eyi ni iranti. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu oju ona kan to de odo Oluwa re |
۞ إِنَّ رَبَّكَ يَعْلَمُ أَنَّكَ تَقُومُ أَدْنَىٰ مِن ثُلُثَيِ اللَّيْلِ وَنِصْفَهُ وَثُلُثَهُ وَطَائِفَةٌ مِّنَ الَّذِينَ مَعَكَ ۚ وَاللَّهُ يُقَدِّرُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ ۚ عَلِمَ أَن لَّن تُحْصُوهُ فَتَابَ عَلَيْكُمْ ۖ فَاقْرَءُوا مَا تَيَسَّرَ مِنَ الْقُرْآنِ ۚ عَلِمَ أَن سَيَكُونُ مِنكُم مَّرْضَىٰ ۙ وَآخَرُونَ يَضْرِبُونَ فِي الْأَرْضِ يَبْتَغُونَ مِن فَضْلِ اللَّهِ ۙ وَآخَرُونَ يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۖ فَاقْرَءُوا مَا تَيَسَّرَ مِنْهُ ۚ وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ وَأَقْرِضُوا اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا ۚ وَمَا تُقَدِّمُوا لِأَنفُسِكُم مِّنْ خَيْرٍ تَجِدُوهُ عِندَ اللَّهِ هُوَ خَيْرًا وَأَعْظَمَ أَجْرًا ۚ وَاسْتَغْفِرُوا اللَّهَ ۖ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (20) Dajudaju Oluwa re mo pe dajudaju iwo n dide kirun fun ohun t’o kere si ilata meji oru tabi ilaji re tabi ilata re. Igun kan ninu awon t’o wa pelu re (naa n se bee). Allahu l’O n sodiwon oru ati osan. O si mo pe e ko le so o. Nitori naa, O ti da a pada si fifuye fun yin. Nitori naa, e ke ohun ti o ba rorun (fun yin) ninu al-Ƙur’an. O mo pe awon alaisan yoo wa ninu yin. Awon miiran si n ririn ajo lori-ile, ti won n wa ninu oore Allahu. Awon miiran si n jagun fun esin Allahu. Nitori naa, e ke ohun ti o ba rorun (fun yin) ninu re. E kirun (oran-an-yan). E yo Zakah. Ki e si ya Allahu ni dukia t’o dara. Ohunkohun ti e ba ti siwaju fun emi ara yin ninu ohun rere, eyin yoo ba a lodo Allahu ni ohun rere ati ni ohun ti o tobi julo ni esan. E toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |