Quran with Yoruba translation - Surah Hud ayat 17 - هُود - Page - Juz 12
﴿أَفَمَن كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّهِۦ وَيَتۡلُوهُ شَاهِدٞ مِّنۡهُ وَمِن قَبۡلِهِۦ كِتَٰبُ مُوسَىٰٓ إِمَامٗا وَرَحۡمَةًۚ أُوْلَٰٓئِكَ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۚ وَمَن يَكۡفُرۡ بِهِۦ مِنَ ٱلۡأَحۡزَابِ فَٱلنَّارُ مَوۡعِدُهُۥۚ فَلَا تَكُ فِي مِرۡيَةٖ مِّنۡهُۚ إِنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴾
[هُود: 17]
﴿أفمن كان على بينة من ربه ويتلوه شاهد منه ومن قبله كتاب﴾ [هُود: 17]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ǹjẹ́ ẹni t’ó ń bẹ́ lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (ìyẹn, Ànábì s.a.w.), tí olùjẹ́rìí kan (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) sì ń ké al-Ƙur’ān (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn), (ǹjẹ́ Ànábì yìí jọ olùṣìnà bí?) Àwọn (mùsùlùmí) wọ̀nyí ni wọ́n sì gbà á gbọ́ ní òdodo. Ẹnikẹ́ni t’ó bá ṣàì gbà á gbọ́ nínú àwọn ìjọ (nasara, yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ), nígbà náà Iná ni àdéhùn rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa al-Ƙur’ān. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́ |