Quran with Yoruba translation - Surah Yusuf ayat 77 - يُوسُف - Page - Juz 13
﴿۞ قَالُوٓاْ إِن يَسۡرِقۡ فَقَدۡ سَرَقَ أَخٞ لَّهُۥ مِن قَبۡلُۚ فَأَسَرَّهَا يُوسُفُ فِي نَفۡسِهِۦ وَلَمۡ يُبۡدِهَا لَهُمۡۚ قَالَ أَنتُمۡ شَرّٞ مَّكَانٗاۖ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا تَصِفُونَ ﴾
[يُوسُف: 77]
﴿قالوا إن يسرق فقد سرق أخ له من قبل فأسرها يوسف في﴾ [يُوسُف: 77]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Wọ́n sọ pé: “Tí ó bá jalè, dájúdájú ọmọ-ìyá rẹ̀ kan ti jalè ṣíwájú.” (Ànábì) Yūsuf sì fi ọ̀rọ̀ náà pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ̀, kò sì fi hàn sí wọn pé (kò rí bẹ́ẹ̀). Ó (sì) sọ pé: “Ipò tiyín l’ó buru jùlọ. Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ.” |