Quran with Yoruba translation - Surah Ibrahim ayat 9 - إبراهِيم - Page - Juz 13
﴿أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ نَبَؤُاْ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ قَوۡمِ نُوحٖ وَعَادٖ وَثَمُودَ وَٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لَا يَعۡلَمُهُمۡ إِلَّا ٱللَّهُۚ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَرَدُّوٓاْ أَيۡدِيَهُمۡ فِيٓ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَقَالُوٓاْ إِنَّا كَفَرۡنَا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ وَإِنَّا لَفِي شَكّٖ مِّمَّا تَدۡعُونَنَآ إِلَيۡهِ مُرِيبٖ ﴾
[إبراهِيم: 9]
﴿ألم يأتكم نبأ الذين من قبلكم قوم نوح وعاد وثمود والذين من﴾ [إبراهِيم: 9]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ṣé ìró àwọn t’ó ṣíwájú yín kò tí ì dé ba yín ni? Ìjọ (Ànábì) Nūh, ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd àti àwọn t’ó wá lẹ́yìn wọn; kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Allāhu. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nígbà náà, wọ́n ti ọwọ́ wọn bọ ẹnu wọn (ní ti ìbínú), wọ́n sì wí pé: "Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú n̄ǹkan tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́. Àti pé dájúdájú àwa wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí |