Quran with Yoruba translation - Surah Maryam ayat 58 - مَريَم - Page - Juz 16
﴿أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ مِن ذُرِّيَّةِ ءَادَمَ وَمِمَّنۡ حَمَلۡنَا مَعَ نُوحٖ وَمِن ذُرِّيَّةِ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡرَٰٓءِيلَ وَمِمَّنۡ هَدَيۡنَا وَٱجۡتَبَيۡنَآۚ إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُ ٱلرَّحۡمَٰنِ خَرُّواْۤ سُجَّدٗاۤ وَبُكِيّٗا۩ ﴾
[مَريَم: 58]
﴿أولئك الذين أنعم الله عليهم من النبيين من ذرية آدم وممن حملنا﴾ [مَريَم: 58]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Isrọ̄’īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún |