Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 124 - البَقَرَة - Page - Juz 1
﴿۞ وَإِذِ ٱبۡتَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِـۧمَ رَبُّهُۥ بِكَلِمَٰتٖ فَأَتَمَّهُنَّۖ قَالَ إِنِّي جَاعِلُكَ لِلنَّاسِ إِمَامٗاۖ قَالَ وَمِن ذُرِّيَّتِيۖ قَالَ لَا يَنَالُ عَهۡدِي ٱلظَّٰلِمِينَ ﴾
[البَقَرَة: 124]
﴿وإذ ابتلى إبراهيم ربه بكلمات فأتمهن قال إني جاعلك للناس إماما قال﴾ [البَقَرَة: 124]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa fi àwọn ọ̀rọ̀ kan dán (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wò. Ó sì parí wọn ní pípé. (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Èmi yó ṣe ọ́ ní aṣíwájú fún àwọn ènìyàn.” (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Àti nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi.” (Allāhu) sọ pé: "Àdéhùn Mi (láti sọ ẹnì kan di Òjíṣẹ́) kò níí tẹ àwọn alábòsí lọ́wọ́ |