Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 15 - البَقَرَة - Page - Juz 1
﴿ٱللَّهُ يَسۡتَهۡزِئُ بِهِمۡ وَيَمُدُّهُمۡ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ ﴾
[البَقَرَة: 15]
﴿الله يستهزئ بهم ويمدهم في طغيانهم يعمهون﴾ [البَقَرَة: 15]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Allāhu máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sì máa mú wọn lékún sí i nínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà. tí àwọn ìṣe náà jẹ́ ìṣe t’ó dúró sórí fífi orúkọ ìṣe ẹ̀dá sọ orúkọ ẹ̀san ìṣe náà. Irú rẹ̀ l’ó ṣẹlẹ̀ nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í ṣe olùṣeyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ó máa ń ṣe yẹ̀yẹ́) tàbí oníyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ẹ̀dá lè fi ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹnì kan kò sì níí máa ṣe yẹ̀yẹ́ àfi kí ó jẹ́ aláwàdà oníranù. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í ṣe àwàdà Allāhu kì í ṣe ẹlẹ́tàn. Ẹnì kan kò níí jẹ́ ẹlẹ́tàn àfi kí ó jẹ́ òpùrọ́ olùyapa-àdéhùn. Allāhu kì í ṣe òpùrọ́. Allāhu gan-an ni Òdodo. Bákan náà |