Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 184 - البَقَرَة - Page - Juz 2
﴿أَيَّامٗا مَّعۡدُودَٰتٖۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٖ فَعِدَّةٞ مِّنۡ أَيَّامٍ أُخَرَۚ وَعَلَى ٱلَّذِينَ يُطِيقُونَهُۥ فِدۡيَةٞ طَعَامُ مِسۡكِينٖۖ فَمَن تَطَوَّعَ خَيۡرٗا فَهُوَ خَيۡرٞ لَّهُۥۚ وَأَن تَصُومُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴾
[البَقَرَة: 184]
﴿أياما معدودات فمن كان منكم مريضا أو على سفر فعدة من أيام﴾ [البَقَرَة: 184]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Ẹ gba ààwẹ̀ náà) fún àwọn ọjọ́ tí ó ní òǹkà. (Ṣùgbọ́n) ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ó wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) ní àwọn ọjọ́ mìíràn. Àti pé ìtánràn (ìyẹn) fífún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ l’ó di dandan fún àwọn t’ó máa fi ìnira gba ààwẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fínnúfíndọ̀ ṣe (àlékún) iṣẹ́ olóore, ó kúkú lóore jùlọ fún un. Àti pé kí ẹ gba ààwẹ̀ lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀ |