Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 197 - البَقَرَة - Page - Juz 2
﴿ٱلۡحَجُّ أَشۡهُرٞ مَّعۡلُومَٰتٞۚ فَمَن فَرَضَ فِيهِنَّ ٱلۡحَجَّ فَلَا رَفَثَ وَلَا فُسُوقَ وَلَا جِدَالَ فِي ٱلۡحَجِّۗ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ يَعۡلَمۡهُ ٱللَّهُۗ وَتَزَوَّدُواْ فَإِنَّ خَيۡرَ ٱلزَّادِ ٱلتَّقۡوَىٰۖ وَٱتَّقُونِ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ ﴾
[البَقَرَة: 197]
﴿الحج أشهر معلومات فمن فرض فيهن الحج فلا رفث ولا فسوق ولا﴾ [البَقَرَة: 197]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí A ti mọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà, kò gbọdọ̀ sí oorun ìfẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ dídá àti àríyànjiyàn nínú iṣẹ́ Hajj. Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe ní rere, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ẹ mú èsè ìrìn-àjò lọ́wọ́. Dájúdájú èsè ìrìn-àjò t’ó lóore jùlọ ni ìṣọ́ra (níbi èsè ẹlòmíìràn àti agbe ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ Hajj). Ẹ bẹ̀rù Mi, ẹ̀yin onílàákàyè |