Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 235 - البَقَرَة - Page - Juz 2
﴿وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِيمَا عَرَّضۡتُم بِهِۦ مِنۡ خِطۡبَةِ ٱلنِّسَآءِ أَوۡ أَكۡنَنتُمۡ فِيٓ أَنفُسِكُمۡۚ عَلِمَ ٱللَّهُ أَنَّكُمۡ سَتَذۡكُرُونَهُنَّ وَلَٰكِن لَّا تُوَاعِدُوهُنَّ سِرًّا إِلَّآ أَن تَقُولُواْ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗاۚ وَلَا تَعۡزِمُواْ عُقۡدَةَ ٱلنِّكَاحِ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ ٱلۡكِتَٰبُ أَجَلَهُۥۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِيٓ أَنفُسِكُمۡ فَٱحۡذَرُوهُۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ حَلِيمٞ ﴾
[البَقَرَة: 235]
﴿ولا جناح عليكم فيما عرضتم به من خطبة النساء أو أكننتم في﴾ [البَقَرَة: 235]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ pẹ́sọ nínú ìbánisọ̀rọ̀ ìfẹ́ tàbí tí ẹ fi pamọ́ sínú ẹ̀mí yín. Allāhu mọ̀ pé dájúdájù ẹ̀yin yó máa rántí wọn, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀, àyàfi pé kí ẹ máa sọ ọ̀rọ̀ dáadáa. Ẹ má ṣe pinnu ìta kókó yìgì títí àsìkò (opó) máa fi parí. Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Rẹ̀. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà |