Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 246 - البَقَرَة - Page - Juz 2
﴿أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلۡمَلَإِ مِنۢ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ مِنۢ بَعۡدِ مُوسَىٰٓ إِذۡ قَالُواْ لِنَبِيّٖ لَّهُمُ ٱبۡعَثۡ لَنَا مَلِكٗا نُّقَٰتِلۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۖ قَالَ هَلۡ عَسَيۡتُمۡ إِن كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡقِتَالُ أَلَّا تُقَٰتِلُواْۖ قَالُواْ وَمَا لَنَآ أَلَّا نُقَٰتِلَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَقَدۡ أُخۡرِجۡنَا مِن دِيَٰرِنَا وَأَبۡنَآئِنَاۖ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقِتَالُ تَوَلَّوۡاْ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنۡهُمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّٰلِمِينَ ﴾
[البَقَرَة: 246]
﴿ألم تر إلى الملإ من بني إسرائيل من بعد موسى إذ قالوا﴾ [البَقَرَة: 246]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ṣé o ò rí àwọn aṣíwájú nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl, lẹ́yìn (ìgbà Ànábì) Mūsā? Nígbà tí wọ́n wí fún Ànábì tiwọn pé: “Yan ọba kan fún wa, kí á lọ jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu.” Ó sọ pé: “Ṣebí ó ṣe é ṣe pé tí Wọ́n bá ṣe ogun jíjà ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí tán ẹ ò kúkú níí jagun?” Wọ́n wí pé: "Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ láti jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu? Wọ́n kúkú ti lé àwa àti àwọn ọmọ wa jáde kúrò nínú ilé wa!" Àmọ́ nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí tán, wọ́n pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí |