Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 283 - البَقَرَة - Page - Juz 3
﴿۞ وَإِن كُنتُمۡ عَلَىٰ سَفَرٖ وَلَمۡ تَجِدُواْ كَاتِبٗا فَرِهَٰنٞ مَّقۡبُوضَةٞۖ فَإِنۡ أَمِنَ بَعۡضُكُم بَعۡضٗا فَلۡيُؤَدِّ ٱلَّذِي ٱؤۡتُمِنَ أَمَٰنَتَهُۥ وَلۡيَتَّقِ ٱللَّهَ رَبَّهُۥۗ وَلَا تَكۡتُمُواْ ٱلشَّهَٰدَةَۚ وَمَن يَكۡتُمۡهَا فَإِنَّهُۥٓ ءَاثِمٞ قَلۡبُهُۥۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ عَلِيمٞ ﴾
[البَقَرَة: 283]
﴿وإن كنتم على سفر ولم تجدوا كاتبا فرهان مقبوضة فإن أمن بعضكم﴾ [البَقَرَة: 283]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àti pé tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò, tí ẹ̀yin kò sì rí akọ̀wé, ẹ gba ohun ìdógò. (Ṣùgbọ́n) tí apá kan yín bá fi ọkàn tán apá kan, kí ẹni tí wọ́n fi ọkàn tán dá ohun tí wọ́n fi ọkàn tán an lé lórí padà, kí ó sì bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Ẹ má ṣe fi ẹ̀rí pamọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi pamọ́, dájúdájú ọkàn rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe |