Quran with Yoruba translation - Surah Al-Anbiya’ ayat 8 - الأنبيَاء - Page - Juz 17
﴿وَمَا جَعَلۡنَٰهُمۡ جَسَدٗا لَّا يَأۡكُلُونَ ٱلطَّعَامَ وَمَا كَانُواْ خَٰلِدِينَ ﴾
[الأنبيَاء: 8]
﴿وما جعلناهم جسدا لا يأكلون الطعام وما كانوا خالدين﴾ [الأنبيَاء: 8]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni A kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kò níí jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé). abara ni kì í ṣe ọlọ́hun. Allāhu àwọn òkú kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè ní ìbámu sí sūrah an-Naml; 27:80 sūrah ar-Rūm; 30:52 àti sūrah Fātir; 35:22. Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì padà di òkú tí wọ́n bò mọ́ inú sàréè nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ ní ìbámu sí sūrah az-Zumọr; 39:30. Kò sì sí āyah tààrà kan nínú al-Ƙur’ān tí ó yọ Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sílẹ̀ nínú àwọn òkú tí kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè. Àmọ́ hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé “Kò sí ẹnì kan tí ó máa sálámọ̀ sí mi àfi kí Allāhu dá ẹ̀mí mi padà sí mi lára títí mo máa fi dá sálámọ̀ náà padà fún un.” Abū Dāūd l’ó gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb ziyāratul-ƙubūr. Ṣeek al-Bāniy sọ pé “hadīth náà dára”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy. Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé “Dájúdájú ọjọ́ Jum‘ah wà nínú àwọn ọjọ́ yín t’ó lóore jùlọ; Wọ́n ṣẹ̀dá Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú rẹ̀ ní ìṣẹ̀lẹ̀ t’ó tayọ òye wa àmọ́ tí ó tẹnu Ànábì wa Muhammad olódodo (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jáde tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín.” Ẹnì kan nínú àwọn t’ó gba hadīth yìí wá sọ pé “Kí ni ìtúmọ̀ “tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín”? Tàbí kí ni ìtúmọ̀ “tí ohun tí ó máa fi darí yín sì máa wá láti ọ̀dọ̀ yín?” Ibnu Abī Thanb sì fèsì pé |