Quran with Yoruba translation - Surah An-Nur ayat 33 - النور - Page - Juz 18
﴿وَلۡيَسۡتَعۡفِفِ ٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ نِكَاحًا حَتَّىٰ يُغۡنِيَهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦۗ وَٱلَّذِينَ يَبۡتَغُونَ ٱلۡكِتَٰبَ مِمَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡ فَكَاتِبُوهُمۡ إِنۡ عَلِمۡتُمۡ فِيهِمۡ خَيۡرٗاۖ وَءَاتُوهُم مِّن مَّالِ ٱللَّهِ ٱلَّذِيٓ ءَاتَىٰكُمۡۚ وَلَا تُكۡرِهُواْ فَتَيَٰتِكُمۡ عَلَى ٱلۡبِغَآءِ إِنۡ أَرَدۡنَ تَحَصُّنٗا لِّتَبۡتَغُواْ عَرَضَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَمَن يُكۡرِههُّنَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ مِنۢ بَعۡدِ إِكۡرَٰهِهِنَّ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴾
[النور: 33]
﴿وليستعفف الذين لا يجدون نكاحا حتى يغنيهم الله من فضله والذين يبتغون﴾ [النور: 33]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Kí àwọn tí kò rí (owó láti fẹ́) ìyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.1 Àwọn t’ó ń wá ìwé òmìnira nínú àwọn ẹrú yín, ẹ kọ ìwé òmìnira fún wọn tí ẹ bá mọ ohun rere nípa wọn. Kí ẹ sì fún wọn nínú dúkìá Allāhu tí Ó fun yín. (Nítorí dúkìá ayé tí ẹ̀ ń wá), ẹ má ṣe jẹ àwọn ẹrúbìnrin yín nípá láti lọ ṣe sìná, tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.2 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ wọ́n nípá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ wọ́n nípá |