Quran with Yoruba translation - Surah al-‘Imran ayat 13 - آل عِمران - Page - Juz 3
﴿قَدۡ كَانَ لَكُمۡ ءَايَةٞ فِي فِئَتَيۡنِ ٱلۡتَقَتَاۖ فِئَةٞ تُقَٰتِلُ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَأُخۡرَىٰ كَافِرَةٞ يَرَوۡنَهُم مِّثۡلَيۡهِمۡ رَأۡيَ ٱلۡعَيۡنِۚ وَٱللَّهُ يُؤَيِّدُ بِنَصۡرِهِۦ مَن يَشَآءُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةٗ لِّأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ ﴾
[آل عِمران: 13]
﴿قد كان لكم آية في فئتين التقتا فئة تقاتل في سبيل الله﴾ [آل عِمران: 13]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àmì kúkú wà fun yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn). Ìjọ kan ń jà fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Ìkejì sì jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ìjọ kejì ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú. Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùrìran |