Quran with Yoruba translation - Surah al-‘Imran ayat 152 - آل عِمران - Page - Juz 4
﴿وَلَقَدۡ صَدَقَكُمُ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥٓ إِذۡ تَحُسُّونَهُم بِإِذۡنِهِۦۖ حَتَّىٰٓ إِذَا فَشِلۡتُمۡ وَتَنَٰزَعۡتُمۡ فِي ٱلۡأَمۡرِ وَعَصَيۡتُم مِّنۢ بَعۡدِ مَآ أَرَىٰكُم مَّا تُحِبُّونَۚ مِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلدُّنۡيَا وَمِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلۡأٓخِرَةَۚ ثُمَّ صَرَفَكُمۡ عَنۡهُمۡ لِيَبۡتَلِيَكُمۡۖ وَلَقَدۡ عَفَا عَنكُمۡۗ وَٱللَّهُ ذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴾
[آل عِمران: 152]
﴿ولقد صدقكم الله وعده إذ تحسونهم بإذنه حتى إذا فشلتم وتنازعتم في﴾ [آل عِمران: 152]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Dájúdájú Allāhu ti mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fun yín nígbà tí ẹ̀ ń pa wọ́n pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀, títí di ìgbà tí ẹ fi ṣojo, tí ẹ sì ń jiyàn sí ọ̀rọ̀. Ẹ sì yapa (àṣẹ Ànábì) lẹ́yìn tí Allāhu fi ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí hàn yín. - Ó wà nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ayé, ó sì ń bẹ nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ọ̀run. - Lẹ́yìn náà, (Allāhu) yí ojú yín kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, kí Ó lè dan yín wò. Ó sì ti ṣàmójú kúrò fun yín; Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo |