Quran with Yoruba translation - Surah al-‘Imran ayat 45 - آل عِمران - Page - Juz 3
﴿إِذۡ قَالَتِ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَٰمَرۡيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكِ بِكَلِمَةٖ مِّنۡهُ ٱسۡمُهُ ٱلۡمَسِيحُ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ وَجِيهٗا فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَمِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ ﴾
[آل عِمران: 45]
﴿إذ قالت الملائكة يامريم إن الله يبشرك بكلمة منه اسمه المسيح عيسى﴾ [آل عِمران: 45]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: "Mọryam, dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa dídá ẹ̀dá kan pẹ̀lú) ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Abiyì ni ní ayé àti ní ọ̀run. Ó sì wà lára alásùn-únmọ́ (Allāhu). nínú āyah ti āli ‘Imrọ̄n Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa bí àwọn mọlā’ikah ṣe wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbi ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àwọn mọlāika t’ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà ju ẹyọ kan lọ. Ìdí nìyí tí “mọlā’ikah” fi jẹ́ ọ̀pọ̀ nínú āyah yẹn. Àmọ́ nínú āyah ti Mọryam |