Quran with Yoruba translation - Surah Luqman ayat 32 - لُقمَان - Page - Juz 21
﴿وَإِذَا غَشِيَهُم مَّوۡجٞ كَٱلظُّلَلِ دَعَوُاْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ فَلَمَّا نَجَّىٰهُمۡ إِلَى ٱلۡبَرِّ فَمِنۡهُم مُّقۡتَصِدٞۚ وَمَا يَجۡحَدُ بِـَٔايَٰتِنَآ إِلَّا كُلُّ خَتَّارٖ كَفُورٖ ﴾
[لُقمَان: 32]
﴿وإذا غشيهم موج كالظلل دعوا الله مخلصين له الدين فلما نجاهم إلى﴾ [لُقمَان: 32]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Nígbà tí ìgbì omi bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru bí àwọn àpáta àti ẹ̀ṣújò, wọ́n á pe Allāhu (gẹ́gẹ́ bí) olùṣàfọ̀mọ́-àdúà fún Un. Nígbà tí Ó bá sì gbà wọ́n là sórí ilẹ̀, onídéédé sì máa wà nínú wọn. Kò sì sí ẹni t’ó máa tako àwọn āyah Wa àfi gbogbo ọ̀dàlẹ̀, aláìmoore |