Quran with Yoruba translation - Surah FaTir ayat 40 - فَاطِر - Page - Juz 22
﴿قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ شُرَكَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُواْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ لَهُمۡ شِرۡكٞ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ أَمۡ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ كِتَٰبٗا فَهُمۡ عَلَىٰ بَيِّنَتٖ مِّنۡهُۚ بَلۡ إِن يَعِدُ ٱلظَّٰلِمُونَ بَعۡضُهُم بَعۡضًا إِلَّا غُرُورًا ﴾
[فَاطِر: 40]
﴿قل أرأيتم شركاءكم الذين تدعون من دون الله أروني ماذا خلقوا من﴾ [فَاطِر: 40]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn òrìṣà yín tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹ fi ohun tí wọ́n dá hàn mí lórí ilẹ̀? Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) níbi (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Tàbí A fún wọn ní tírà kan, tí wọ́n ní ẹ̀rí t’ó yanjú nínú rẹ̀? Rárá o! Kò sí àdéhùn kan tí àwọn alábòsí, apá kan wọn ń ṣe fún apá kan bí kò ṣe ẹ̀tàn.” |