Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 25 - النِّسَاء - Page - Juz 5
﴿وَمَن لَّمۡ يَسۡتَطِعۡ مِنكُمۡ طَوۡلًا أَن يَنكِحَ ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ فَمِن مَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُم مِّن فَتَيَٰتِكُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۚ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِإِيمَٰنِكُمۚ بَعۡضُكُم مِّنۢ بَعۡضٖۚ فَٱنكِحُوهُنَّ بِإِذۡنِ أَهۡلِهِنَّ وَءَاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِ مُحۡصَنَٰتٍ غَيۡرَ مُسَٰفِحَٰتٖ وَلَا مُتَّخِذَٰتِ أَخۡدَانٖۚ فَإِذَآ أُحۡصِنَّ فَإِنۡ أَتَيۡنَ بِفَٰحِشَةٖ فَعَلَيۡهِنَّ نِصۡفُ مَا عَلَى ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ مِنَ ٱلۡعَذَابِۚ ذَٰلِكَ لِمَنۡ خَشِيَ ٱلۡعَنَتَ مِنكُمۡۚ وَأَن تَصۡبِرُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡۗ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴾
[النِّسَاء: 25]
﴿ومن لم يستطع منكم طولا أن ينكح المحصنات المؤمنات فمن ما ملكت﴾ [النِّسَاء: 25]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹni tí kò bá lágbára ọrọ̀ nínú yín láti fẹ́ àwọn olómìnira onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, kí ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúbìnrin yín, onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ yín, ara kan náà (sì) ni yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda àwọn olówó wọn. Kí ẹ sì fún wọn ní sọ̀daàkí wọn ní ọ̀nà t’ó dára, (ìyẹn) àwọn ọmọlúàbí (ẹrúbìnrin), yàtọ̀ sí àwọn aṣẹ́wó àti ọ̀dọ́kọ. Nígbà tí wọ́n bá sì di abilékọ, tí wọ́n bá (tún) lọ ṣe sìná, ìlàjì ìyà tí ń bẹ fún àwọn olómìnira ni ìyà tí ń bẹ fún wọn. (Fífẹ́ ẹrúbìnrin), ìyẹn wà fún ẹni t’ó ń páyà ìnira (sìná) nínú yín. Àti pé kí ẹ ṣe sùúrù lóore jùlọ fun yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run |