Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 32 - النِّسَاء - Page - Juz 5
﴿وَلَا تَتَمَنَّوۡاْ مَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بِهِۦ بَعۡضَكُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۚ لِّلرِّجَالِ نَصِيبٞ مِّمَّا ٱكۡتَسَبُواْۖ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٞ مِّمَّا ٱكۡتَسَبۡنَۚ وَسۡـَٔلُواْ ٱللَّهَ مِن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا ﴾
[النِّسَاء: 32]
﴿ولا تتمنوا ما فضل الله به بعضكم على بعض للرجال نصيب مما﴾ [النِّسَاء: 32]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹ má ṣe jẹ̀rankàn ohun tí Allāhu fi ṣ’oore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan. Ìpín (ẹ̀san) ń bẹ fún àwọn ọkùnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, ìpín (ẹ̀san) sì ń bẹ fún àwọn obìnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Kí ẹ sì tọrọ lọ́dọ̀ Allāhu àlékún oore Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan |