Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 89 - النِّسَاء - Page - Juz 5
﴿وَدُّواْ لَوۡ تَكۡفُرُونَ كَمَا كَفَرُواْ فَتَكُونُونَ سَوَآءٗۖ فَلَا تَتَّخِذُواْ مِنۡهُمۡ أَوۡلِيَآءَ حَتَّىٰ يُهَاجِرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۚ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَخُذُوهُمۡ وَٱقۡتُلُوهُمۡ حَيۡثُ وَجَدتُّمُوهُمۡۖ وَلَا تَتَّخِذُواْ مِنۡهُمۡ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرًا ﴾
[النِّسَاء: 89]
﴿ودوا لو تكفرون كما كفروا فتكونون سواء فلا تتخذوا منهم أولياء حتى﴾ [النِّسَاء: 89]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Wọ́n fẹ́ kí ẹ ṣàì gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́, kí ẹ lè jọ di ẹgbẹ́ kan náà. Nítorí náà, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò nínú wọn títí wọ́n fi máa ṣí kúrò nínú ìlú ẹbọ wá sí ìlú ’Islām fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Tí wọ́n bá kẹ̀yìn (sí ṣíṣe hijrah náà), ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ẹ bá ti rí wọn. Kí ẹ sì má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò àti olùrànlọ́wọ́ kan nínú wọn |