Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 94 - النِّسَاء - Page - Juz 5
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا ضَرَبۡتُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَتَبَيَّنُواْ وَلَا تَقُولُواْ لِمَنۡ أَلۡقَىٰٓ إِلَيۡكُمُ ٱلسَّلَٰمَ لَسۡتَ مُؤۡمِنٗا تَبۡتَغُونَ عَرَضَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا فَعِندَ ٱللَّهِ مَغَانِمُ كَثِيرَةٞۚ كَذَٰلِكَ كُنتُم مِّن قَبۡلُ فَمَنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمۡ فَتَبَيَّنُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا ﴾
[النِّسَاء: 94]
﴿ياأيها الذين آمنوا إذا ضربتم في سبيل الله فتبينوا ولا تقولوا لمن﴾ [النِّسَاء: 94]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò ogun ẹ̀sìn Allāhu, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn). Ẹ sì má ṣe sọ fún ẹni tí ó bá sálámọ̀ si yín pé kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo nítorí pé ẹ̀yin ń wá dúkìá ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu kúkú ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ ogun wà. Báyẹn ni ẹ̀yin náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, Allāhu sì ṣe ìdẹ̀ra (ẹ̀sìn) fun yín. Nítorí náà, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn náà). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ |