Quran with Yoruba translation - Surah Ghafir ayat 67 - غَافِر - Page - Juz 24
﴿هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ مِنۡ عَلَقَةٖ ثُمَّ يُخۡرِجُكُمۡ طِفۡلٗا ثُمَّ لِتَبۡلُغُوٓاْ أَشُدَّكُمۡ ثُمَّ لِتَكُونُواْ شُيُوخٗاۚ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ مِن قَبۡلُۖ وَلِتَبۡلُغُوٓاْ أَجَلٗا مُّسَمّٗى وَلَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ ﴾
[غَافِر: 67]
﴿هو الذي خلقكم من تراب ثم من نطفة ثم من علقة ثم﴾ [غَافِر: 67]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè |