Quran with Yoruba translation - Surah Al-Fath ayat 29 - الفَتح - Page - Juz 26
﴿مُّحَمَّدٞ رَّسُولُ ٱللَّهِۚ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥٓ أَشِدَّآءُ عَلَى ٱلۡكُفَّارِ رُحَمَآءُ بَيۡنَهُمۡۖ تَرَىٰهُمۡ رُكَّعٗا سُجَّدٗا يَبۡتَغُونَ فَضۡلٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنٗاۖ سِيمَاهُمۡ فِي وُجُوهِهِم مِّنۡ أَثَرِ ٱلسُّجُودِۚ ذَٰلِكَ مَثَلُهُمۡ فِي ٱلتَّوۡرَىٰةِۚ وَمَثَلُهُمۡ فِي ٱلۡإِنجِيلِ كَزَرۡعٍ أَخۡرَجَ شَطۡـَٔهُۥ فَـَٔازَرَهُۥ فَٱسۡتَغۡلَظَ فَٱسۡتَوَىٰ عَلَىٰ سُوقِهِۦ يُعۡجِبُ ٱلزُّرَّاعَ لِيَغِيظَ بِهِمُ ٱلۡكُفَّارَۗ وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ مِنۡهُم مَّغۡفِرَةٗ وَأَجۡرًا عَظِيمَۢا ﴾
[الفَتح: 29]
﴿محمد رسول الله والذين معه أشداء على الكفار رحماء بينهم تراهم ركعا﴾ [الفَتح: 29]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Muhammad ni Òjíṣẹ́ Allāhu. Àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́, aláàánú sì ni wọ́n láààrin ara wọn. O máa rí wọn ní olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun), tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Àmì wọn wà ní ojú wọn níbi orípa ìforíkanlẹ̀. Ìyẹn ni àpèjúwe wọn nínú Taorāh àti àpèjúwe wọn nínú ’Injīl, gẹ́gẹ́ bí kóró èso igi t’ó yọ ọ̀gọ́mọ̀ rẹ̀ jáde. Lẹ́yìn náà, ó nípọn (ó lágbára), ó sì dúró gbagidi lórí igi rẹ̀. Ó sì ń jọ àwọn àgbẹ̀ lójú. (Allāhu fi àyè gba Ànábì àti àwọn Sọhābah rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi wọ́n ṣe ohun ìbínú fún àwọn aláìgbàgbọ́. Allāhu ṣàdéhùn àforíjìn àti ẹ̀san ńlá fún àwọn t’ó gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere nínú wọn |