Quran with Yoruba translation - Surah Al-Ma’idah ayat 5 - المَائدة - Page - Juz 6
﴿ٱلۡيَوۡمَ أُحِلَّ لَكُمُ ٱلطَّيِّبَٰتُۖ وَطَعَامُ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ حِلّٞ لَّكُمۡ وَطَعَامُكُمۡ حِلّٞ لَّهُمۡۖ وَٱلۡمُحۡصَنَٰتُ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ وَٱلۡمُحۡصَنَٰتُ مِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكُمۡ إِذَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ مُحۡصِنِينَ غَيۡرَ مُسَٰفِحِينَ وَلَا مُتَّخِذِيٓ أَخۡدَانٖۗ وَمَن يَكۡفُرۡ بِٱلۡإِيمَٰنِ فَقَدۡ حَبِطَ عَمَلُهُۥ وَهُوَ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ ﴾
[المَائدة: 5]
﴿اليوم أحل لكم الطيبات وطعام الذين أوتوا الكتاب حل لكم وطعامكم حل﴾ [المَائدة: 5]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fun yín lónìí. Àti oúnjẹ àwọn tí A fún ní tírà, ẹ̀tọ́ ni fun yín.1 Oúnjẹ tiyín náà, ẹ̀tọ́ ni fún wọn. (Ẹ̀tọ́ ni fun yín láti fẹ́) àwọn olómìnira nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin àti àwọn olómìnira lóbìnrin nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín, nígbà tí ẹ bá ti fún wọn ní ṣọ̀daàkí wọn; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ (bí ’Islām ṣe ní kí ẹ fẹ́ ìyàwó), láì níí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì) láì sì níí yàn wọ́n lálè.2 Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí ìgbàgbọ́ òdodo, iṣẹ́ rẹ̀ ti bàjẹ́. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò. òrìṣà ìbẹ̀rẹ̀ àti ìdáwọ́lé kan tí àwọn òyìnbó abọ̀rìṣà ń pè ní Janus ni wọ́n fi gbé oṣù àti ọdún January kalẹ̀. Àwọn kristiẹni sì tẹ́wọ́ gbà á lọ́wọ́ wọn. Mùsùlùmí yó sì máa jẹ́ mùsùlùmí lórí gbígba ọ̀rọ̀ Allāhu gbọ́ ní òdodo. Tí irú mùsùlùmí yìí bá tún wá bá àwọn kristiẹni dá sí ọdún January láì sì ṣíjú wo àwọn ewu ńlá tí kò ṣe é jànìyàn t’ó tún rọ̀ mọ́ ìgbéyàwó. Dandan sì ni fún wa láti lo āyah papọ̀ mọ́ra wọn ní ọ̀nà tí kò fi níí já sí pé mùsùlùmí tẹ̀lé ìtúmọ̀ ojú-ọ̀rọ̀ nìkan ní ìyapa sí ìtúmọ̀ ojú ọ̀rọ̀ mìíràn. Ní àkọ́kọ́ ná nínú sūrah al-Baƙọrah |